6 Mo gbé ejika rẹ̀ kuro ninu ẹrù: mo si gbà agbọn li ọwọ rẹ̀.
7 Iwọ pè ninu ipọnju, emi si gbà ọ; emi da ọ lohùn nibi ìkọkọ ãra: emi ridi rẹ nibi omi ija.
8 Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si jẹri si ọ: Israeli, bi iwọ ba fetisi mi.
9 Kì yio si ọlọrun miran ninu nyin; bẹ̃ni iwọ kì yio sìn ọlọrun àjeji.
10 Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti jade wá: yà ẹ̀nu rẹ̀ gbòro, emi o si kún u.
11 Ṣugbọn awọn enia mi kò fẹ igbọ́ ohùn mi; Israeli kò si fẹ ti emi.
12 Bẹ̃ni mo fi wọn silẹ fun lile aiya wọn: nwọn si nrìn ninu ero ara wọn.