3 Nwọn ti gbimọ̀ arekereke si awọn enia rẹ, nwọn si ti gbèro si awọn ẹni-ìkọ̀kọ̀ rẹ.
4 Nwọn ti wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a ke wọn kuro lati má wà li orilẹ-ède; ki orukọ Israeli ki o máṣe si ni iranti mọ́.
5 Nitoriti nwọn ti gbimọ̀ pọ̀ ṣọkan: nwọn ti dimọlu si ọ.
6 Agọ Edomu, ati ti awọn ọmọ Iṣmaeli; ti Moabu, ati awọn ọmọ Hagari.
7 Gebali, ati Ammoni, ati Amaleki: awọn ara Filistia pẹlu awọn ara Tire;
8 Assuri pẹlu dapọ̀ mọ wọn: nwọn ràn awọn ọmọ Lotu lọwọ.
9 Ṣe wọn bi o ti ṣe awọn ara Midiani; bi Sisera, bi Jabini, li odò Kiṣoni.