5 Nitoriti nwọn ti gbimọ̀ pọ̀ ṣọkan: nwọn ti dimọlu si ọ.
6 Agọ Edomu, ati ti awọn ọmọ Iṣmaeli; ti Moabu, ati awọn ọmọ Hagari.
7 Gebali, ati Ammoni, ati Amaleki: awọn ara Filistia pẹlu awọn ara Tire;
8 Assuri pẹlu dapọ̀ mọ wọn: nwọn ràn awọn ọmọ Lotu lọwọ.
9 Ṣe wọn bi o ti ṣe awọn ara Midiani; bi Sisera, bi Jabini, li odò Kiṣoni.
10 Ẹniti o ṣegbe ni Endori: nwọn di àtan fun ilẹ.
11 Ṣe awọn ọlọla wọn bi Orebu ati bi Sebu: ani, gbogbo awọn ọmọ-alade wọn bi Seba ati Salmuna.