2 Ọkàn mi nfà nitõtọ, o tilẹ pe ongbẹ fun agbala Oluwa: aiya mi ati ara mi nkigbe si Ọlọrun alãye.
3 Nitõtọ, ologoṣẹ ri ile, ati alapandẹdẹ tẹ́ itẹ fun ara rẹ̀, nibiti yio gbe ma pa awọn ọmọ rẹ̀ mọ́ si, ani ni pẹpẹ rẹ wọnni, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọba mi ati Ọlọrun mi.
4 Ibukún ni fun awọn ti ngbe inu ile rẹ: nwọn o ma yìn ọ sibẹ.
5 Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ: li ọkàn ẹniti ọ̀na rẹ wà.
6 Awọn ti nla afonifoji omije lọ, nwọn sọ ọ di kanga; akọrọ-òjo si fi ibukún bò o.
7 Nwọn nlọ lati ipá de ipá, ni Sioni ni awọn yọ niwaju Ọlọrun.
8 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, gbọ́ adura mi; fi eti si i, Ọlọrun Jakobu.