3 Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ.
4 Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá.
5 Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran?
6 Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ?
7 Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ.
8 Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were.
9 Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa.