1 OLUWA Ọlọrun igbala mi, emi nkigbe lọsan ati loru niwaju rẹ.
2 Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ: dẹ eti rẹ silẹ si igbe mi.
3 Nitori ti ọkàn mi kún fun ipọnju, ẹmi mi si sunmọ isa-okú.
4 A kà mi pẹlu kún awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: emi dabi ọkunrin ti kò ni ipá.