15 Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère.
16 Ifẹju ibinu rẹ kọja lara mi; ìbẹru rẹ ti ke mi kuro.
17 Nwọn wá yi mi ka li ọjọ gbogbo bi omi: nwọn yi mi kakiri tan.
18 Olufẹ ati ọrẹ ni iwọ mu jina si mi, ati awọn ojulumọ mi ninu okunkun.