4 A kà mi pẹlu kún awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: emi dabi ọkunrin ti kò ni ipá.
5 Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ.
6 Iwọ ti fi mi le ibi isalẹ ti o jìn julọ, ninu okunkun, ninu ọgbun.
7 Ibinu rẹ lẹ̀ mọ mi lara kikan, iwọ si ti fi riru omi rẹ gbogbo ba mi ja.
8 Iwọ ti mu awọn ojulumọ mi jina si mi; iwọ si sọ mi di irira si wọn; a se mi mọ́, emi kò le jade.
9 Oju mi nkãnu nitori ipọnju: Oluwa, emi ti npè ọ lojojumọ, emi si ti nawọ mi si ọ.
10 Iwọ o fi iṣẹ iyanu rẹ hàn fun okú bi? awọn okú yio ha dide ki nwọn si ma yìn ọ bi?