13 Ṣãnu fun mi, Oluwa; rò iṣẹ́ ti emi nṣẹ́ lọwọ awọn ti o korira mi, iwọ ti o gbé ori mi soke kuro li ẹnu-ọ̀na ikú.
14 Ki emi ki o le ma fi gbogbo iyìn rẹ hàn li ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin Sioni, emi o ma yọ̀ ni igbala rẹ.
15 Awọn orilẹ-ède jìn sinu ọ̀fin ti nwọn wà: ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ́.
16 A mọ̀ Oluwa, nipa idajọ ti o nṣe: nipa iṣẹ ọwọ enia buburu li a fi ndẹkùn mu u.
17 Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun.
18 Nitori pe a kì yio gbagbe awọn alaini lailai: abá awọn talaka kì yio ṣegbe lailai.
19 Oluwa, dide; máṣe jẹ ki enia ki o bori: jẹ ki a ṣe idajọ awọn orilẹ-ède niwaju rẹ.