17 Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun.
18 Nitori pe a kì yio gbagbe awọn alaini lailai: abá awọn talaka kì yio ṣegbe lailai.
19 Oluwa, dide; máṣe jẹ ki enia ki o bori: jẹ ki a ṣe idajọ awọn orilẹ-ède niwaju rẹ.
20 Dẹru ba wọn, Oluwa: ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ ara wọn pe, enia ṣa ni nwọn.