5 Iwọ ba awọn orilẹ-ède wi, iwọ pa awọn enia buburu run, iwọ pa orukọ wọn rẹ́ lai ati lailai.
6 Niti ọta, iparun wọn pari tan lailai: iwọ li o si ti run ilu wọnni; iranti wọn si ti ṣegbe pẹlu wọn.
7 Ṣugbọn Oluwa yio wà titi lailai: o ti tẹ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ fun idajọ.
8 On o si ṣe idajọ aiye li ododo, yio ṣe idajọ fun awọn enia li otitọ ìwa.
9 Oluwa ni yio ṣe àbo awọn ẹni-inilara, àbo ni igba ipọnju.
10 Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ.
11 Ẹ kọrin iyìn si Oluwa, ti o joko ni Sioni: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.