3 Nitori Oluwa, Ọlọrun ti o tobi ni, ati Ọba ti o tobi jù gbogbo oriṣa lọ,
4 Ni ikawọ ẹniti ibi ọgbun ilẹ wà: giga awọn òke nla ni tirẹ̀ pẹlu.
5 Tirẹ̀ li okun, on li o si dá a: ọwọ rẹ̀ li o si dá iyangbẹ ilẹ.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ ki a wolẹ, ki a tẹriba: ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa, Ẹlẹda wa.
7 Nitori on li Ọlọrun wa; awa si li enia papa rẹ̀, ati agutan ọwọ rẹ̀. Loni bi ẹnyin o ba gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 Ẹ má sé aiya nyin le, bi ti Meriba ati bi ọjọ na ni Massa, li aginju.
9 Nigbati awọn baba nyin dan mi wò, ti nwọn wadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi.