7 Nitori on li Ọlọrun wa; awa si li enia papa rẹ̀, ati agutan ọwọ rẹ̀. Loni bi ẹnyin o ba gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 Ẹ má sé aiya nyin le, bi ti Meriba ati bi ọjọ na ni Massa, li aginju.
9 Nigbati awọn baba nyin dan mi wò, ti nwọn wadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi.
10 Ogoji-ọdun tọ̀tọ ni inu mi fi bajẹ si iran na, mo ni, Enia ti o ṣina li aiya ni nwọn, nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi:
11 Awọn ẹniti mo si bura fun ni ibinu mi pe, nwọn ki yio wọ ibi isimi mi.