10 Ẹ wi lãrin awọn keferi pe, Oluwa jọba: nitõtọ a o fi idi aiye mulẹ ti kì yio le yẹ̀: on o fi ododo ṣe idajọ enia.
11 Jẹ ki ọrun ki o yọ̀, jẹ ki inu aiye ki o dùn; jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀.
12 Jẹ ki oko ki o kún fun ayọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: nigbana ni gbogbo igi igbo yio ma yọ̀.
13 Niwaju Oluwa: nitoriti mbọwa, nitori ti mbọwa ṣe idajọ aiye: yio fi ododo ṣe idajọ aiye, ati ti enia ni yio fi otitọ rẹ̀ ṣe.