4 Nitori ti Oluwa tobi, o si ni iyìn pupọ̀pupọ̀: on li o ni ìbẹru jù gbogbo oriṣa lọ.
5 Nitori pe gbogbo oriṣa orilẹ-ède asan ni nwọn: ṣugbọn Oluwa li o da ọrun.
6 Ọlá ati ọla-nla li o wà niwaju rẹ̀: ipa ati ẹwà mbẹ ninu ibi mimọ́ rẹ̀.
7 Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipá fun Oluwa.
8 Ẹ fi ogo fun orukọ Oluwa: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá si agbala rẹ̀.
9 Ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́: ẹ wariri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye.
10 Ẹ wi lãrin awọn keferi pe, Oluwa jọba: nitõtọ a o fi idi aiye mulẹ ti kì yio le yẹ̀: on o fi ododo ṣe idajọ enia.