5 Jẹ ki awọn enia mimọ́ ki o kún fun ayọ̀ ninu ogo; ki nwọn ki o mã kọrin kikan lori ẹni wọn.
6 Ki iyìn Ọlọrun ki o wà li ẹnu wọn, ati idà oloju meji li ọwọ wọn;
7 Lati san ẹsan lara awọn keferi, ati ijiya lara awọn enia.
8 Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọba wọn, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè awọn ọlọ̀tọ wọn;
9 Lati ṣe idajọ wọn, ti a ti kọwe rẹ̀, ọlá yi ni gbogbo enia mimọ́ rẹ̀ ni. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.