3 Ẹnyin o ti ma rọlu enia kan pẹ to? gbogbo nyin li o fẹ pa a: bi ogiri ti o bìwó ati bi ọgbà ti nwó lọ.
4 Kiki ìro wọn ni lati já a tilẹ kuro ninu ọlá rẹ̀: nwọn nṣe inu didùn ninu eke: nwọn nfi ẹnu wọn sure, ṣugbọn nwọn ngegun ni inu wọn.
5 Ọkàn mi, iwọ sa duro jẹ de Ọlọrun; nitori lati ọdọ rẹ̀ wá ni ireti mi.
6 On nikan li apata mi ati igbala mi: on li àbo mi; a kì yio ṣi mi ni ipò.
7 Nipa Ọlọrun ni igbala mi, ati ogo mi: apata agbara mi, àbo mi si mbẹ ninu Ọlọrun.
8 Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa.
9 Nitõtọ asan li awọn ọmọ enia, eke si li awọn oloyè. Nwọn gòke ninu ìwọn, bakanna ni nwọn fẹrẹ jù asan lọ.