1 FI eti silẹ, ẹnyin enia mi, si ofin mi: dẹ eti nyin silẹ si ọ̀rọ ẹnu mi.
2 Emi o ya ẹnu mi li owe: emi o sọ ọ̀rọ atijọ ti o ṣokunkun jade.
3 Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa.
4 Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ.
5 Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn.
6 Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn: