2 Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní;jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ.
3 Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀,Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA.
4 Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀,kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀.
5 Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un.Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ;ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6 Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú,ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro.
7 Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀;ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
8 Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé,níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀;ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa.