8 Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé,níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀;ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa.
9 Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba;ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀;ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ.
10 Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba,ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú.
11 Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé,OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.”
12 Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i;má sì gbàgbé àwọn tí a nilára.
13 Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun,tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?”
14 Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan,nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà,kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san;nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé,ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba.