12 Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́,wọ́n sì kọrin yìn ín.
13 Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀.
14 Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀,wọ́n sì dán Ọlọrun wò.
15 Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè,ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n.
16 Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó,ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.
17 Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀.
18 Iná sọ láàrin wọn,ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.