14 Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀,wọ́n sì dán Ọlọrun wò.
15 Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè,ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n.
16 Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó,ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.
17 Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀.
18 Iná sọ láàrin wọn,ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.
19 Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà.
20 Wọ́n gbé ògo Ọlọrunfún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.