20 Wọ́n gbé ògo Ọlọrunfún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,
22 ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu,ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa.
23 Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run,bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀,tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀,láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.
24 Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA.
25 Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.
26 Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọnpé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀,