24 Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA.
25 Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.
26 Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọnpé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀,
27 ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiriàwọn orílẹ̀-èdè.
28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.
29 Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú,àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.
30 Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.