30 Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.
31 A sì kà á kún òdodo fún un,láti ìrandíran títí lae.
32 Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba,wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose,
33 nítorí wọ́n mú Mose bínú,ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.
34 Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run,gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn,
35 ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà,wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.
36 Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn,èyí sì fa ìpalára fún wọn.