35 ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà,wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.
36 Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn,èyí sì fa ìpalára fún wọn.
37 Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa.
38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin,ati ti àwọn ọmọbinrin wọn,tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani;wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́.
39 Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè.
40 Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀.
41 Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́,títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí.