4 Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ńṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ.Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là.
5 Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹkí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ,kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ.
6 A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa,a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú.
7 Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti,wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ,wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó.Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa.
8 Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀;kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn.
9 Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀.
10 Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.