40 Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀.
41 Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́,títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí.
42 Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára,wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn.
43 Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀,ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i,OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44 Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn,nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn.
45 Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá,ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
46 Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn.