44 Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn,nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn.
45 Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá,ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
46 Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn.
47 Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa,kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.