6 A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa,a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú.
7 Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti,wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ,wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó.Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa.
8 Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀;kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn.
9 Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀.
10 Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
11 Omi bo àwọn ọ̀tá wọn,ẹyọ ẹnìkan kò sì là.
12 Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́,wọ́n sì kọrin yìn ín.