12 Kí ó má bá aláàánú pàdé,kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba.
13 Kí ìran rẹ̀ run,kí orúkọ rẹ̀ parẹ́ lórí àwọn ọmọ rẹ̀.
14 Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀,kí ó má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ rẹ́.
15 Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbà gbogbo,kí á má sì ranti ìran wọn mọ́ láyé.
16 Nítorí pé kò ronú láti ṣàánú,ṣugbọn ó ṣe inúnibíni talaka ati aláìní,ati sí oníròbìnújẹ́ títí a fi pa wọ́n.
17 Ó fẹ́ràn láti máa ṣépè;nítorí náà kí èpè rẹ̀ dà lé e lórí;inú rẹ̀ kò dùn sí ìre,nítorí náà kí ìre jìnnà sí i.
18 Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù,kí èpè mù ún bí omi,kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn.