19 Kí èpè di aṣọ ìbora fún un,ati ọ̀já ìgbànú.
20 Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi,àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi!
21 Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà minítorí orúkọ rẹ, gbà mí!Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀.
22 Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí,ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ.
23 Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́,a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú.
24 Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà,mo rù kan egungun.
25 Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi,wọ́n ń wò mí ní àwòmirí.