21 Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà minítorí orúkọ rẹ, gbà mí!Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀.
22 Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí,ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ.
23 Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́,a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú.
24 Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà,mo rù kan egungun.
25 Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi,wọ́n ń wò mí ní àwòmirí.
26 Ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, Ọlọrun mi,gbà mí, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni èyí,kí wọn mọ̀ pé, ìwọ OLUWA ni o ṣe é.