4 Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí,sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn.
5 Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi,ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.
6 Yan eniyan burúkú tì í,jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́.
7 Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀,jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi;kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn.
8 Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú,kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà.
9 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba,kí aya rẹ̀ di opó.
10 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká,kí wọn máa ṣagbe kiri;kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé.