6 Yan eniyan burúkú tì í,jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́.
7 Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀,jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi;kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn.
8 Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú,kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà.
9 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba,kí aya rẹ̀ di opó.
10 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká,kí wọn máa ṣagbe kiri;kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé.
11 Kí ẹni tí ó jẹ lówó gba gbogbo ohun ìní rẹ̀,kí ẹni ẹlẹ́ni sì kó èrè iṣẹ́ rẹ̀.
12 Kí ó má bá aláàánú pàdé,kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba.