1 Ẹ yin OLUWA!N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn,láàrin àwọn olódodo,ati ní àwùjọ àwọn eniyan.
2 Iṣẹ́ OLUWA tóbi,àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri.
3 Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo,òdodo rẹ̀ sì wà títí lae.
4 OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀.
5 A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀,a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae.
6 Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀,nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.