4 OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀.
5 A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀,a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae.
6 Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀,nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà,gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú.
8 Wọ́n wà títí lae ati laelae,ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin.
9 Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀,ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae,mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀.
10 Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé.Títí lae ni ìyìn rẹ̀.