1 Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti,tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì,
2 Juda di ilé mímọ́ rẹ̀,Israẹli sì di ìjọba rẹ̀.
3 Òkun rí i, ó sá,Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn.
4 Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò,àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan.
5 Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun?Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani?