5 Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun?Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani?
6 Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò?Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan?
7 Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀,wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu.
8 Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi,tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.