3 Ọlọrun wa wà ní ọ̀run,ó ń ṣe ohun tí ó wù ú.
4 Fadaka ati wúrà ni ère tiwọn,iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.
5 Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran.
6 Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn,wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn.
7 Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó,wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin.
8 Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn,bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn.
9 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.