6 Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn,wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn.
7 Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó,wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin.
8 Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn,bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn.
9 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.
10 Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.
11 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ gbẹ́kẹ̀lé e,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.
12 OLUWA ranti wa, yóo bukun wa,yóo bukun ilé Israẹli,yóo bukun ìdílé Aaroni.