14 N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA,lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.
15 Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA.
16 OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́,iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ.O ti tú ìdè mi.
17 N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ,n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA.
18 N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWAlójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀,
19 ninu àgbàlá ilé OLUWA,láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu.Ẹ máa yin OLUWA!