15 Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA.
16 OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́,iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ.O ti tú ìdè mi.
17 N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ,n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA.
18 N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWAlójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀,
19 ninu àgbàlá ilé OLUWA,láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu.Ẹ máa yin OLUWA!