3 Tàkúté ikú yí mi ká;ìrora isà òkú dé bá mi;ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀.
4 Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA,mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!”
5 Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA,aláàánú ni Ọlọrun wa.
6 OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́;nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí.
7 Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá,nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ.
8 Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú,o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé,o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú.
9 Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè.