9 Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè.
10 Igbagbọ mi kò yẹ̀, nígbà tí mo tilẹ̀ wí pé,“Ìpọ́njú dé bá mi gidigidi.”
11 Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé,“Èké ni gbogbo eniyan.”
12 Kí ni n óo san fún OLUWA,nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí mi?
13 N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA,n óo sì pe orúkọ rẹ̀.
14 N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA,lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.
15 Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA.