1 OLUWA ni mo ké pè, nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,ó sì dá mi lóhùn.
2 OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké,ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn.
3 Kí ni a óo fi san án fun yín?Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn?
4 Ọfà mímú ni a óo ta yín,a óo sì dáná sun yín.