1 Mo gbójú sókè wo àwọn òkè,níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá?
2 Ìrànlọ́wọ́ mi ń ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá,ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.
3 Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀,ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé.
4 Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn.
5 OLUWA ni olùpamọ́ rẹ.OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ.
6 Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru.
7 OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi,yóo pa ọ́ mọ́.