4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà,àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ,láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWAgẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli.
5 Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí,àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi.
6 Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu!“Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ!
7 Kí alaafia ó wà ninu rẹ,kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.”
8 Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi,n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.”
9 Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa,èmi óo máa wá ire rẹ.