1 Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa,ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,
2 “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wanígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá,
3 wọn ìbá gbé wa mì láàyè,nígbà tí inú bí wọn sí wa;
4 àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ,ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀;
5 ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.”
6 Ọpẹ́ ni fún OLUWA,tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn.