1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni,tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae.
2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.
3 Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹlórí ilẹ̀ àwọn olódodo,kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi.
4 OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere,ati fún àwọn olódodo.